Ilé Oba tó n’jó now, now… by Odolaye Aremu

Reading Time: 2 minutes

[Ero]–Papa mi to gbayì! Ę ku rásmóńbógé to gb’òde kan yi o! Ę pęlę! Wòbótà! Kóyo! Ìgbé’rhàn ehn! Papa mii t’ęę ba gęęti mi, èdè Edo ni mi fi nki yin yęn! Áftáròòluù awon Oloye yin tun ti riliisi awijare tuntun. Iyen tun l’omori! Erimosélekè ni!

Won ni: Èkó kii se’lę Yooba! Won ni Bini tun lo ja ìbálé ęyin ara Eko!

Emi kędę ni wipe ki n’sere wa gba Senji dię lowo yin ni mo tun ri wipe eefin nru lori ruufu Ìgà a yin! Mi tię koko ro wipe ę ti ngba’na sori l’osan gangan yi ni, ori mi koko gbona tori mi ranti wipe, mi ti woonu yin kęę ma maa sa tafé lęyin mi as padi to padi! Ajoję sęę geeti, lo maa ndun!

A fi bimi se ri Olori ti won dę fo lat’oju ferese ile’dana won jade si titi Adeniji Adele, ti won dę téekoofù bii eni ti ara Ejigbo na ni oruka ànàsáré! Ibę ni mi ti mo wipe, ina to njo yi ki’se ina seréseré, ki dę kii se ti kùkúyè rara! Bęt, mi gbo wipe awon boisi ru yin jade nnu Dísíkò Ìnfànò yęn laaye, lai’farapa! Edumare seun!

Papa mi, mi maa adufaisi yin kęę lo apolojaisi fun boisi Ooni yen o! Bikoos Eegun Atiro wole, Isikilu Atiro jade sita, dajudaju ogun ìdílé ti n’àféétì Isikilu! Maalu oniwo sarasara ko dę ni l’eyin loju ala o! Àsę!

Ni ipari, owe ilu yin naa ni maa fi ęndi lęta wèrè ti mo ko si yin yi! Ę kędę tun n’bimi wipe “Ilu yin wo?!” Ę kędę saa tun ti so wipe Bini tun ni awon ansesitoosi yin ti wa! Ológbón lo kędę dę maa ye, awon Òmòràn kędę lo maa ęfęnsuali gęęti ę!

“AI WE WEN OVBOKHIAN GHE RU AKON GAI, SOKPA O GHI MIEN AKHUARAMWEN NWU’YA GUERE!”

Emi n’tiyin n’tooto
Odolaye Saburi Aremu
Nomba 2, Ileobatonjolowo
Afijio, Fiditi.
Ipinlę Oyo
Copyright 2017 The Page. Permission to use quotations from this article is granted subject to appropriate credit being given to www.thepageng.com as the source.

Comments

comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *