Ìgbeyàwó Kénà ati Igbeyawo Miná: Ìyàtò? by Odolaye Aremu

Reading Time: 5 minutes

[Ero]–Jesu Kristi àkóbí Josefu ati Maria n’mura, o dabi eni wipe abami ęda yi fęę r’ode iyawo:

Olugbala wo dàńdógó, o wo sapará, o wo sokoto kan ti won ran ni t’alábę. Ko kuku bikita, o wo salubata jatijati kan lee, o mu ìborùn aso Téru iya’a re kan bayi ti onitohun fi se ęgbęjoda ngbakanri, o fi pa kájà, o b’oode. Afi bii wipe sitaili imura omo Maria ni Òjájá Akoko, Arole Oduduwa ji wo! Jesu ya ile Peteru, o de’le Johannu omo ęhanna kan bayi to fęran Omo Maria bii Dòdò Ìkirè. Won kuro nibe, won ya’le Timotiu, won pe Tomoosi nidi igi Osè ti yun’un ti nta ayo olópón, won tun pade Saakiu danku baba Imole lona. Saakiu agbowó-òde naa tele won leyin! Ka maa d’eena p’ęnu, gbogbo awon oloriire ati wèrè ęda ti won ko Omo maria lona ni won tęle e de Kana, nbi Olugbala ti so omi lasan di otíi Wáìnì! Idi eyi lo fi l’ęto ki òpònú oku’in ma se yara na owó ępòn si obi’in ti eni naa ko baa ti rędi owo iyawo! Oku’in ti o ba le pese Oti lojo ìgbeyàwó ara’a rę f’awon mogbómoyà, walai iru oku’in bęę ti se tęribu misiteeki! Ìgbeyàwó ti o ba ti l’ótí n’nu, gbàfùèlè n’iru iyawo bęę! Opélopé Jesu!

Ìgbeyàwó Miná:

Okan n’nu awon omo Balogun Ole Agbaye n’se ‘gbeyawo, o ti daju wipe gbogbo awon mejoriti awon Ole to ku n’gboro ni won o wa lori ijoko. Tori wipe, l’ojo isinku Ajanaku, orisirisi awon Òbę lo l’ęto ko p’eju, ki won pésè! Sebi ngba Adebayo Sosęęsi n’se idana omo re n’josi, gbogbo awon awako, omo eyin okò pelu awon eeria boisi lo peju?! Won royin wipe, ose kan tiwon fi se faaji n’le Adebayo, gbogbo igboro lo gb’afęfę alaafia yato s’awon omo Asewo at’awon Oniparaga n’diko! Asęwo o ri kósítómà. Awon Oniparaga naa o kuku le maa da mu oti ara won!

Gbàdàmósí Màràdónà, Balogun awon Ole ilu f’ile pon’ti, Alokólóhunkígbe yi f’ona r’oka o pe gbogbo awon Alájàpá bii tię ki won wa ba ohun yo! Dele Giwa o kuku farabalę duro l’aye sin’mo re’le oko bęę ko f’eyawo f’omo o! Sebi Gbada naa kuku ni o je k’omo olomo o roju r’aaye r’omo omo e! Won pa Dele danu ni bii Ewúré ti won s’ebè Ęgusi sinu agbada ti won fi ogunlogo àdó olóró dękoreeti si fun! Opo awon Soja ti won ku s’inu irà Èjìgbò ni won o tii l’aya d’epo won o s’eyawo f’omo!

Gbada ti j’ale j’ale ogbologbo Olósà ti wa d’eni ti nfi Akómonírìn rin bii ikoko l’arugbo ara! Bo şe n’sun to nji laarin awon Oku ti won nrin kiri laarin aafin ę lori oke Jebba gan o yemi! Awon omo ti won pa ti won fi s’òrun àjìjà o kuku l’ounka! Awon ole bii tię na wa lati ilu Eko, Oyo, Ogun, Ondo, Ekiti, Enúgu, Kàlàba ati jakejado orileede Naijeria! Olorun nikan lo mo’ye Maalu tio s’oriibu nibi àpèjè oriibu yi! Ogogoro, Sękętę, Otíkà ati awon otí Eebo orisirisi ni mo fura wipe won o pade ara won naa nbe!

Nibi ti Olugbala Omo Maria ti f’ęsę rin lati Nasaręti de Kénà, won royin wipe awon ìgbìmò ole yi gbe Baalu aladani bii meedogbon lo si Mina. Won o kuku le rin bii Jesu, bęę won o le gbe moto gba ori koto, ori gegele bii awa Ajírébi! Ibi Jesu ti sise iyanu akoko ni Kena, to so omi di oti Wáìnì, awon Karanbani ęda yi ti ję, won ti yo. Ti Jesu gan o baa ręęspęęti araa rę won o bo yo won o gbe sori kétékété l’óòró pada si Násárétì ni!

Emi kan tię ìmájìn ki ado Oloro kan abi meji ti won gbe pęęli dię kan sadede jabo le gbogbo won lori lojiji, ki gbogbo awon ota ilu wa o gba’be jade sasaraelu, ki Jesu kan bawa seefu t’oko t’aya tuntun ki won baa le gbon’mi si Ketemfe ara won lale ojo ìgbeyàwó won! Boya ilu wa o tię gbadun dię! Boya afefe alaafia o ti fe siwa n’le Naijeria!
Gęgębi omo elépo, a yaa tun’go wa fo!

N e s’apaayan o, imajínéshòn ori’bu ni o j’emi naa o rìlàásì o!

Awon Oloriibu dede!

Odolaye Saburi Aremu is a social observer, commentator and an oddball with a usually, unusually perspective on social issues. He’s a retired baby boomer, presently residing at Fiditi, Afijio LGA Oyo State.
Copyright 2017 The Page. Permission to use quotations from this article is granted subject to appropriate credit being given to www.thepageng.com as the source.

Comments

comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *