Fọ́múlà oríire f’áwọn ọmọ òtòsì! By Odòlayé Àrẹ̀mú

Reading Time: 3 minutes

[Erò]–…n’bi ìkómo omo ti won n’pe ni Daanieli un ni mo ti kó fura wipe yoo maa f’éwó abi f’ogbón maa jalè n’gboo ba dàgbà. Ina njo l’órómi, ę yo bimí le’re ibi eérú e wa! Òrò naa ree!

Ìsomolórúko Dino:

Obì ajóòópá kan bayi to dabi ohun ti won rí’he l’ona oko ni mbe nn’u awo. Ti won ba e le fi obi buúkú yi bé’gi fun’yan bayi, adura Adeboye gan o nii le wę èpè ohun nu! Orógbó meji ti nbe nnu awo naa ri hánránhánrán, won dabi awon omoge ti ko jeun ká’nú ti won tun n’lo bílíshíń kiriimù. Awon orógbó èèmò wonyi pupa résúrésú won ri bii ìkóóde Odíderé ti arun opolo nba a ja. Ataare eyo kan to dabi gògòńgò olókùnrùn; afi bii Ataare ti riseshon n’baaja ninu oko. Ęyo kan péré naa si mbe nbe! Oyin ti won bu sinu awo; walai ko lee kun ìdérí ìgò kóòkì. Yààsin ńgbó! Ti won ba e fi ika kan’an fi ra omo lenu bayi, dát ìsì dì eèndì! Bęę naa si l’epo pupa. O dabi wipe èyó epo ti e ni. Won ti gbáa dada ki won to ta die sinu awo táńganran. O j’ohun wipe won o r’ówó r’ayò, iyò síún ti won ni n’le n’won dàpò mo súgà, ti won fi kan omo l’enu! Omi kàňga n’won bu sinu igba féléfélé kan bayi. Omi tie l’omi nję na, tii kii ba tii se Omi Ògùnpa tabi ti Kúdętì! Àádùn oríibú kan bayi ti o f’anilójú mó’ra rara naa wa nnu awo. Kayeefi lo waa je funmi wipe, ninu owón gógó awon ohun èròjà ìsomolórúko t’aa kaa’lę yi, Ogogoro lo poju! Nibi ti ko ye ki won nílò ju koopu kan lo, odidi gálóònù mejo ni won ko sorii tabili.

Ę wa n’binu ori, eni k’omo olomo maa loonshi iwe oriibu to ko! Sebi ohun to ba wu ni ju ni n’po lólà eni? Ohun t’eeyan ba sa’a mo daju l’eeyan o ko npa e!

Ogun ngbo, ko s’igba emi naa o ni k’owée temi! Àkólé rę si ni: FÓMÚLÀ ORÍIRE F’AWON OMO ÒTÒSÌ!

*Àròko lasan l’oro temi o! Ikilo pataki f’ęyin Gbékěyíde! Emi o si ba’yan kan wi n’temi o! E mo kobami o! Ogun Lakaaye o ni ko b’eyin naa o!*

Odolaye Saburi Aremu is a social observer, commentator and an oddball with a usually, unusually perspective on social issues. He’s a retired baby boomer, presently residing at Fiditi, Afijio LGA Oyo State.
Copyright 2017 The Page. Permission to use quotations from this article is granted subject to appropriate credit being given to www.thepageng.com as the source.

Comments

comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *