Wakilu! Wakilu! Wakilu! By Odolaye Aremu

Reading Time: 3 minutes

[Ero]–Ęęmelo n’mo pè ó ná?! Ètó o gbogbo eni ti ba n’ję’su ni ko m’umi sii! Ètó gbogbo eni ti ba si n’yata naa ni ko ranju kalè ko f’ęju toto! Emi to nwo yi, tí mo ję Fádà ę gan naa ni ríńgí toonù ìsonu kan bayi l’ówó!

So rii ti Muni, iya ę ba e le sèèsì pe nomba mi bayi, èmi maa n’dun ni bii Sóbalójú Ilu Eko t’awon Afúňjámoponmo ko mómugààrí si l’ówó! Ipade ebí n’won ti wóònù mi wipe: “ki n’jára mo’se orí ęní bii àyànfé Anabi!” Won tèé mómi l’étí wipe ki “n’la kóńdó ìfé mo móómì ę pęlu dílígéènsì!” Wón ní lóòtó ni: “kini a nwi yi dùn ju súgà tí wón lò papò mó oyin lo!”

Olórí Ebí wa Baba Fasila, Onírùgbòn Kàńàfùrù fi ibinu j’ágbe mómi l’ojo naa l’ohun, won ni “èwo wá n’gbe ofo gan an?” “Ori ę buru ni?” “Won n’saa si o ni?” Mo fi suuru dá won l’ohun: “Mo ní rárá!” Òrò ara a mi saa ni won nba mii so! Sugbon mo so fun won n’nu mitini pàjáwìrì yi wipe: “Fóòtì baba mi ni! Èbi won ni o! Awon ni won o kilo fun mi lati kekee wipe:

“b’eeyan ba nję Múké, eeyan maa n’yiinję ni, b’eeyan ba si n’jààdò, eeyan o kii j’ęnu wàmùwàmù, b’eeyan ba si n’wakùsà nko, eeyan o gbodo tęlę gìrìgìrì!

So diafoo- Wakilu mo éfà so wipe n o wóònù ę o! Boo ba ya tètè joini awon ęgbę akorin ni koo ya tètè bèrè, tori boo ba re bęrę si dun bii Túùpú Ęlędę oko kan ngbo o ba fe ‘yawo tan, ti won lé o n’le, walai ę lee k’ęru wale temi o! Lęękan sii, omoku’in maa n’farabale yáta ni, won kii ke bii awon Egbére Èkímògun t’awon omo Oshodi gb’ęní owó ę! Òrò mi ye o, abi ko ye o?!

Sunmoila omo baba Olófì n’won ni won ti àréèsì un lori Ajoke omo Taju Alétílápá aya a rę n’lę Hausa un! Won ni kini a nwi yi gbadùn lara ę wèrè waa n’yata loru, o tun wa n’pariwo l’ede Hausa wipe: “l’ęyin Igbó Súúrú, Aljanna kan o si mo dáyá!”
Nję ti Sunmoila o ti wa baa bayi bi?!
Copyright 2017 The Page. Permission to use quotations from this article is granted subject to appropriate credit being given to www.thepageng.com as the source.

Comments

comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *